Lati awọn Ìpínlẹ Kaduna ati Borno ni ariwa si awọn Ìpínlẹ Èkó ati Rivers ni gusu, ọrọ nipa ààbò jẹ ohun àfiyèsí ni igbé ayé ojoojumọ Nàìjíríà. Ìpò náà ti buru ni àwọn ọdún àìpẹ yi pẹlu ìhalẹmọ àìláàbò tó bẹrẹ lati Boko Haram ati àwọn ìkọlù Ìpínlẹ Isílámù ni Iwọ Oòrùn Áfíríkà ni Ìlà Oòrùn Àríwá, sí jijinigbé fún owó ìtanràn ati àpilẹse iwa ọdaràn jijalè ni Iwọ Oòrùn Àríwá, ati awuyẹwuyẹ fún yiyapa ati jijalè ninu ọkọ oju omi ni ìha Gúsù-Gúsù. Àwọn ara ilu njábọ àiní ààbò lemọlemọ, eyi ti ó se ifàsẹhin fún irinàjò ati ìsòwò jákèjádò orilẹ-èdè náà. Àwọn ohun ti ó tún jẹki awọn ìpènija kọọkan wọnyi sòro si ni àwọn ohun ti ó ni i ṣe pẹlu igbẹkẹlé, pàápàá jùlọ àfiyesi ni ti ìwà ìbàjẹ ati àsìlò agbara awọn agbófinró lori awọn ará ilú.
Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ni ẹkarun ààrẹ Nàìjíríà lẹhin igbati ó ti padà si ijọba tiwa-n-tiwa ni 1999. Òun ni ààrẹ Nàìjíríà àkọkọ, sibẹsibẹ, tó wá si ijọba pẹlu atilẹhin díẹ awọn olùdìbò (bẹẹni àwọn ìpènijà si àwọn àbájáde ìbò náà ntẹsiwájú láti má a wá ọnà wọn sinu ètò ìdájọ Nàìjíríà). Látàrí èyi, ijọba Tinubu ndojukọ isẹ gbigba igbẹkẹlé awọn ara ilú.
Yiyanjú ihalẹmọ ààbo Nàìjíríà jẹ ohun àkọkọse fún ijọba Tinubu, ó sì jẹ ànfààni iyebiye ti iyipada si ijọba tiwa-n-tiwa fi ààyè gbà lati ronu lé lóri ki wọn si se àyẹwò àwọn ètò-ìmúlò ati àwọn ohun àkọkọse ti orilẹ-èdè. Ìjọba tiwa-n-tiwa ati ileri rẹ lati tún orilẹ-èdè se, siwajusi, kò pari si awọn òbìrípo ìdìbò. Dipo bẹẹ, awọn ọmọ Nàìjíríà ni àbẹwẹ lati fún awọn aláṣẹ ni imọràn lori bi wọn se le jẹki ààbò orilẹ-èdè náà dára si. Sísọ àwọn èrò wọnyi di mimọ yóò se pàtàki fún ààbò awọn ara ilú ati nini itẹsiwájú tó se é diwọn lori awọn ileri lati se àtúnse ẹka ààbò.
Pẹlu ẹmí yi, Ibudó Áfíríkà fún Àwọn Ẹkọ Ìlànà bá àwọn amòye ààbò mẹfa Nàìjíríà sọrọ nipa ohun àkọkọṣe tiwọn fún ìmúdárasi ààbò lábẹ ijọba Tinubu:
- ‘Kúnle Adebajo, Onirohin ati Olootu Awọn Ìwádìí, HumAngle
- Idayat Hassan, Oludari, Ibudo fún Tiwa-n-Tiwa ati Ìdàgbàsoke
- Ndubuisi Nwokolo, Alabasepọ ati Ọga Agba, Nextier SPD
- Matthew Page, Alabasepọ Ẹni, Ilé Chatham Pirogiramu Áfíríkà
- Kemi Okenyodo, Olùdásilẹ àti Olùdarí Àgbà, Alábasepọ Ìwọ-Oòrùn Áfíríkà
- Ọgagun Àgba (Afẹhinti) Shehu Yusuf, Jagunjagun Nàìjíríà
Àwọn ohun àkọkọse ati Iṣedúró
Dídínku Ìpalára Awọn ara ilú
Ọpọlọpọ awọn amòye tẹnumọ pé ijọba tuntun le kó ipa púpọ lori ààbò awọn ara ilú ki wọn si ni ànfààni igbẹkẹlé wọn nipa sise àgbékalẹ awọn ètò-ìmúlò lati dábòbò ati f’agbára kún awọn ọmọ Nàìjíríà.
Darí ifojúsùn awọn ẹsọ ààbò si àwọn ibiti àwọn jàndùkú le tètè le kọlù. Nipa tí tètè dábòbo awọn ara ìlú ni àkókò rògbòdìyàn, ààrẹ tuntun le s’àfihàn ifaraẹniji lati dábòbò awọn ara ilu ki ó si yánjú àwọn ìpènijà ọrọ ààbò orilẹ-èdè náà. Ìlànà yi yóò sètò idanimọ, ìdásí, àti ifarahàn awọn agbófinró ni awọn ikorita rògbòdiyàn ti àwọn ẹgbẹ adigun sábà má a nfojúsùn. Ìlànà yi gbọdọ pẹlu ifojúsùn àwọn ọnà gbígbé káàkiri àti awọn agbègbè tí àwọn ènìyàn pọ sí. Àwọn ìkọlù ni irú àwọn agbègbè báwọnyi ní Ìwọ-Oòrùn Àríwá ati Ìlà-Oòrùn Àríwá ti jẹki ìrìnàjò sí awọn agbègbè wọnyi máse jẹki ó se é sọtẹlẹ.
Ifojúsùn àwọn ẹsọ ààbò yóò dúró lori iwifúnni ọtẹlẹmuyẹ tó péye tó sì bọ́ sásikò lati se ìdánimọ àwọn agbègbè tó léwu jùlọ ati àwọn ìhalẹmọ pàtó. Ọmọwé Nwokolo se ifojúsi wipé awọn ológun Nàìjíríà nisisiyi wà ni ipinlẹ 34 ninu awọn ipinlẹ 36 ti orilẹ-èdè náà, èyí tí ó ndábàá ìmúlò àwọn ànfààni lẹkunrẹrẹ láti pín àwọn jagunjagun káàkiri ki wọn le dojúkọ gbogbo àwọn ìhalẹmọ to burú jùlọ ni orilẹ-èdè.
Ó se pataki lati jẹki awọn adari ilú kópa, àwọn ẹgbẹ ara ilú, ati awọn ajùmọjogún miràn ninu ìlànà yi ki wọn le jinlẹ ninu oye àwọn ipenija tó yàtọ ti àwọn agbègbè kọọkan dojúkọ. Iru ajọsepọ yi, siwaju si, njẹki igbẹkẹlé lágbára si, ó nsèrànwọ fún ipinfúnni ìwífúnni, ó sì nfi agbára kún àsepọ láàárin àwùjọ ati awọn agbófinró.
Se itẹnumọ awọn jagunjagun lori ilẹ dipo ikọlu lati ofurufu.Àwọn ará agbègbè mọ awọn jàndùkú ati ibi ipamọ wọn, èyi ti ó jẹ ànfààni fún àwọn agbófinró láti kọlù wọn bi wọn ti ngbiyànjú ki awọn ara ilu ni igbẹkẹlé ninu wọn, ti wọn si wà ni awọn ibi tó léwu. Pẹlu bi àwọn agbófinró se wà káàkiri, ijọba Tinubu gbọdọ lo ànfààni iwifúnni àwọn ọtẹlẹmuyẹ tó se é gbẹkẹlé láti lé àwọn ẹgbẹ adigun kúrò ni àwọn agbègbè wọnyi nipasẹ awọn sise ọgbọn-ẹwẹ tó peléke si.
Ètò-àmúlò yi yóò mu irọrùn bá awọn ara ilú ti wọn ti jiyà lẹhin ọpọlọpọ ọdun ìyàṣọ́tọ̀ ati ìdágunlá awọn agbófinró ni dídáábòbo àwọn ilú lọwọ àwọn jàndùkú. Ìlàna yi gbọdọ papọ pẹlu ìmúkúrò ikọlu ofurufu gẹgẹbi irin-iṣẹ lati dojúkọ awọn ìhalẹmọ abẹlé. Amoye ààbò Nàìjíríà miràn, Ọmọwé Murtala Rufa’i, ti se àtakò ikọlu ofurufu ni Iwọ-Oòrùn Ariwá gẹgẹbi “ìdojukọ àwọn darandaran, isẹrùbàwọn ati fifọnwọn káàkiri, eyi ti ó túbọ safikun òsì àwùjọ àwọn darandaran.” Ọmọwe Rufa’i ti sèkilọ wipé “ikọlù ofurufu sábà má a njási asán, ó sì léwu nitoripé àwọn jàndùkú má a nlo àwọn igbèríko gẹgẹbi ààbò-èniyàn, tí ó tumọsi wipé ó sòro láti yà wọn sọtọ fún ìfojúsùn.”
“Ilọnilọwọgbà, ifirọpò, ati ìwà-ìpa lọwọ awọn ọlọpa Nàìjíríà ati ológun ti sèrànwọ lati dákún àwọn ìbínú tó nfíná mọ ọpọlọpọ àwọn rògbòdìyàn orilẹ-èdè náà.”
Se àtúnse fún ìwà-ìpa ti ẹka ààbò se si àwọn ara ìlú. Matthew Page s’àfiyesi wipé yóò jẹ ilana ati ọgbọn ìdókòwò fún ijọba Tinubu láti “se àlàkalẹ ilànà kan fún àtúnṣe ati ìtánran etò ìdájọ fún awọn ara ilu ati awọn awujọ ti wọn ni imọlára iwa ìkà awọn ologun ati ọlọpa ati awọn ohun mìíràn tó bajẹ.” Orisun àìláàbò fún ọpọlọpọ ọmọ Nàìjíríà (pàápaájulọ ninu awọn ilu rẹ̀) àti ìdènà kan si àlàáfia pipẹtiti ti jẹ ẹka ààbò fúnrarẹ̀. ‘Kunle Adebajo tọkasi wipe ìlọnilọwọgbà, ìfirọpò, àti ìwà-ipa lọwọ awọn ọlọpa Nàìjíríà ati ológun ti sèrànwọ lati sàfikún awọn ibinu ti wọn sokùnfà awọn rògbòdìyàn orilẹ-èdè náà ati agbekalẹ àwọn ìwà-ipá. Àìdọgba àwọn ètò ìsanpadà Nàìjíríà ti isisiyi farahàn lẹhin awọn ẹhónú #EndSARS, ti wọn san miliọnu lọna ọgọrun Naira fún awọn olùfaragbá iwa-ìkà ọlọpa, nigbati wọn si ntẹsiwájú láti timọlé ati láti dẹruba awọn mìíràn.
F’agbára kún kí o sì s’àbójútó awọn ẹgbẹ ìdábòbò ará ìlú. Mímọ rírì ìdíwọ àwọn èniyàn ati ti ohun-àmúlò tí ẹka ààbò Nàìjíríà ndojúkọ, ati ni ibamu pẹlu igbanisisẹ lábẹ ofin, ijọba Tinubu gbọdọ se àyẹwò àwọn ọnà lati pèsè ohun èlò fún awọn agbègbè láti dábòbo ara wọn. Ètò-àmúlò yi yóò se àtúnse àwọn àseyọri ti Ìpinlẹ Borno Civilian Joint Task Force àti Ìpínlẹ Ogun SO-SAFE force fún àwọn agbègbè mìíràn tí wọn ndojúkọ ewu àìláàbò lemọlemọ gẹgẹbi Ìpínlẹ Kaduna ni Ìwọ-Oòrùn Àríwá. Àwọn ologun wọnyi gbọdọ ni idánilẹkọ ki wọn si tẹlé àwose ise ọlọpa àwùjọ láti s’àtẹnumọ ààbò ara ilú ati dín ilòkulò agbara kù lori ara ilú. Láti dábòbò awọn ara ilu fun igbà pipẹ, kó má tún di ìhàlẹmọ mìíràn, ó jẹ dandan ki awọn òsisẹ pàtàki tuntun ní ìtọsọna òfin , abẹwò tó hàn gbangba, ati idánilẹkọ iṣẹ àmọdájú.
Àtúntò Ẹka Ààbò
Nipa gbigba àtúnto ẹka ààbò, Nàìjíríà le se ìmúdárasi nigbati ó nse àtúnkọ ìgbẹkẹlé ninu àwọn ilé-iṣẹ ààbò orilẹ-èdè náà.
Se ìmúdọgba àwọn ohun àmúlò ẹka ààbò pẹlu àwọn ohun àkọkọṣe ààbò orilẹ-èdè. Nàìjíríà ndojukọ ìpenija nini ọkan lara awọn ẹka ààbò tí ijọba nnáwó sí jùlọ ni Áfirikà, sibẹ ó jẹ eyi ti ó ti tiraka lati sàkójọ ati lati se ìyàsọtọ àwọn ohun àmúlò tó yẹ fún ìfijíṣẹ àwọn èsì igbà pipẹ. Ẹgbin, ìbàjẹ, ati álfábẹti àdàlù awọn àjọ àti àwọn ìpín (pupọ eyi ti kò sisẹ tí kò si múnádóko) sè’dásilẹ àwọn ohun tí kò jáfáfá ti wọn jẹ àmúlùmálà àgbékalẹ ààbò náà. Yíyanjú ìpènijà ọdọọdún yi yóò nilò àyẹwò fínnífínní ti àwọn ohun àmúlo ẹka ààbò ati àwọn ìpín wọn. Gẹgẹbi Matthew Page ti s’àkiyesi, ìlànà yi le nilò sise “àfikún isẹ àbójútó ile asòfin [ti ẹka ààbò náà], ìdápadà àwọn ise ohun rírà déedée, ìwọnba igbékalẹ òsisẹ ati awọn ipò ọga, ati ìdínkù ìdíje láàárin ile-isẹ ati ifisòfò ohun àmúlò nipa ìsọdọkan awọn ile-isẹ ààbò.” Ọna kan kíákíá láti tú àwọn ohun àmúlò silẹ ti àwọn amòye sèdánimọ rẹ ni láti siwọ lilo àwọn ọlọpa gẹgẹbi ààbò ara ẹni fún àwọn gbajúmọ Nàìjíríà ki wọn si tún dojukọ awọn isẹ àpínfúnni ọlọpa lori àlàáfià àwọn ara ilu Nàìjíríà.
“Siso àwọn ìpín wọnyi pọ mọ àwọn ipele àìsí ààbò ti mú irẹwẹsi bá wíwá ojútùú si ọrọ àìsí ààbò.”
Gbẹsẹlé ìlo “àwọn àlàkalẹ fún ààbò.” Matthew Page ngbèrò wipe ki ìjọba Tinubu gbẹsẹlé lẹsẹkẹsẹ ìlo àwọn àlàkalẹ ààbò láti le sàkóso dáadáa áwọn ohun àmúlò tó wà fún ààbò. Àwọn àlàkalẹ ààbò ni owó osoosù ti Ile Asòfin Orilẹ-èdè npin fún àwọn gómìnà láti dojúkọ ọrọ ààbò láì máse ìjabọ rẹ. Àwọn ìpínlẹ ti ipele àìsí ààbo wọn ga jù ngba owó púpọ. Iye ti wọn ná ninu àwọn owó wọnyi kò ni isakóso, bẹẹni bi awọn owó náà ti nwọlé ni àwọn adarí ẹgbẹ nlò wọn gẹgẹbi àjẹmọnú lati se ìmúdúró awọn ọmọ ẹgbẹ. Siso àwọn ìpín wọnyi mọ awọn ipele àìláàbò ti mu irẹwẹsi bá dídojúkọ ipenija àìláàbò gẹgẹbi àwọn ajafitafita lodi si iwa ibajẹ ti Nàìjíríà ti se ìkìlọ. Àwọn àlàkalẹ ààbò jẹ ara ogún ti ọpọlọpọ ọdún ijọba ologun amúnisìn fi lélẹ ati awọn ìtàkùn iwà ibajẹ ti wọn ngbélárugẹ.
Se ìmúsẹ àtúntò àwọn ọlọpa gan-an. Àwọn ìdáwọlé lati se àtúntò tòótọ si ẹgbẹ àwọn ọlọpa Nàìjíríà ti má a nkùnà látàrí iye awọn ìgbìmọ ti ààrẹ ati ti ìpínlẹ, awọn ijabọ, ati awọn isedúró àtẹhinwá. Àṣetunṣe àìpẹ yi ati ìpolongo òbiripo yi ni àbájáde àìsiyemeji iwa-ipá ti orilẹ-èdè tẹmọlẹ awọn ẹhónu #EndSARS tó lòdi si iwà ika àwọn ọlọpa. Kemi Okenyodo sakiyesi wipe pupọ ninu àwọn isedúró tí ó jáde lẹhin iwọde ẹgbẹ #EndSARS ti parẹ nitori kò sí ifẹ ti olósèlú. Látàri wipé wọn ti tú ògbólógbo ìpín SARS náà ká, pupọ ninu àwọn ọdaràn rẹ tó burú jùlọ ṣì ńrìn káàkiri àdúgbò. Àtúntò àwọn ọlọpa jẹ iṣẹ àkọkọse fún ọpọlọpọ ọmọ Nàìjíríà – nitorina ó jẹ ànfààni fún ijọba Tinubu lati se àfihàn wipé isàkóso àwọn ọlọpa yóò yàtọ si bi ó se wà tẹlẹ rí.
Gbà sí iṣẹ ki o sì se ìgbéga àwọn òsìsẹ ẹka ààbò gẹgẹbi ìjáfáfá lẹnu iṣẹ. Ìgbanisisẹ ati ìgbéga awọn òsisẹ ààbò tó dúro lori ìmúyẹ yóò jẹ igbélárugẹ fún ìmòye-isẹ ati ijáfáfá, èyi ti ó má a jẹki a ni àwọn agbofinró tó pegedé tó sì faraji. Kemi Okenyodo sọ nipa awọn anfààni si ìmúnádóko latinu “igbanisisẹ tó dárasi, imoye-isẹ, ati awọn ohun elo isesirò nipasẹ awọn ilana yiyan si ipò, ìgbéga, yíyọ kúrò, ati imudarasi isẹ ọlọpa nipasẹ owó osù tó dára si ati awọn àjẹmọnú.” Matthew Page sakọsilẹ iwọnba iye ologun si ọlọpa ati awọn agbékalẹ jagunjagun ti kò jáfáfá ti wọn ti dásilẹ.
Yan ara ilu si ipo adari awọn ile-isẹ ààbò. Yiyan awọn ara ilu amoye si awọn ipo adari ni ẹka ààbò yóò se é se lati mu ohun tuntun wá ati ilana gbogbogbòò yóò si fifun ààbo Nàìjírà lágbára. Gẹgẹbi Ndubuisi Nwokolo se sàlàyé, “ẹ jẹki [irú àwọn ìgbanisisẹ bawọnyi] jẹ ti ọmọwe, ẹniti ó le mu ìrònú tuntun wá si ètò ààbò wa, nitoripe ni gbogbo igbà ni a nronu ọrọ ààbò gẹgẹbi ọrọ ìbọn ati ọta ìbọn. Bawo ni ti awọn ọran nipa ààbò èniyàn? A kò ni ikọbiarasi ní ti ààbò ati sisọ awọn ohun tí kò rìn. … Ó jẹ iyipadà kékeré tí ó le ni imọlára nla.”
Setò ìlànà lati bori àwọn ìdènà ìgbékalẹ. Síse ojúlówó àtúntò ẹka ààbò yóò nilò lati se idánimọ awọn ìdènà ìsèlú ati ilana, ati sise ètò ilana lati bori wọn. Ọgagun Àgbà Yusuf sọ otitọ nipa ọrọ yi: “àwọn ìdènà yóò wà si àtúntò lati ọdọ awọn tí wọn njẹ ànfààni nibi ètò isisiyi.” Matthew Page faramọ, ó sàfikún wipé iyipadà yóò nilo “ìfẹ òlóselú láti se bẹẹ ni ipele gíga ati ààrẹ tí ó setan lati sètò tí ó si ri àwòrán ètò àtúntò ẹka ààbò ti a gbé kalẹ láti bori àtakò tó le wá lati ẹka ààbò ati lati ọdọ awọn adari oloselu ti wọn njẹ ànfààni latibẹ.” Ọna kan lati dojukọ isoro yi tààrà, Page ndábàá, ni láti se àtúnse si “Òfin Awọn Ológun lati fi agbára fún Ajọ Ipẹjọ Ẹ̀ṣẹ̀ Ọrọ Ajé ati Isúná Owó (EFCC) ti Nàìjíríà ati Àjọ fún Ìpẹjọ Ẹ̀ṣẹ̀ Ìwà Ìbàjẹ ati Awọn Ẹ̀ṣẹ̀ Mìíràn (ICPC) [awọn mejeeji ti wọn ti gba ijiya fún iwa ibàjẹ ti òsèlú ni àìpẹ awọn ọdun yi] lati sèwádìí ki wọn se ìpẹjọ awọn ologun fún iwa ibajẹ.”
Se àtúnkọ́ Ìgbẹkẹlé
Niwọn igbati ó jẹ wipé pupọ ìhalẹmọ ààbò Nàìjíríà ló jẹ ti abẹlé, ifọwọsowọpọ awọn ara ìlú se kókó lati se ìdánimọ awọn agbatẹrù iwa ipá ati wíwá awọn ìdáhùn pipẹ ti awọn àwùjọ abẹlé yóò gbárùkùtì. Kíkọ́ igbẹkẹlé pẹlu awọn ara ilú, látàrí èyí, gbọdọ jẹ kókó ati àkọkọ ohun àmúse ti ètò ààbò orilẹ-èdè ti ijọba Tinubu.
“Ilànà sise ètò ààbò orilẹ-èdè jẹ ànfààni láti sedásilẹ àjọpin iran orilẹ-èdè.”
Gba àsepapọ ìlànà ààbò orilẹ-èdè kan. Bi a ti mọ orisirisi awọn ihalẹmọ ààbò tó ndojúkọ Nàìjíríà, sise àgbékalẹ àpapọ ìlànà ààbò orilẹ-èdè pẹlu àwọn ojútùú tuntun ti a lò fún ọkọọkan awọn ihalẹmọ ààbò Nàìjíríà le pèsè àgbékalẹ lẹsẹẹsẹ fún ifojúsùn ètò ara ilu àti imúsẹ ìgbìyànjú yi. Ìlànà sise ètò ààbò orilẹ-èdè tún jẹ ànfààni lati sèdásilẹ àjọpin iran orilẹ-èdè fún bi ètò ààbò tó múnádóko fún Nàìjíríà yóò se rí. Wíwá ati sise àpapọ gbogbo ìlọwọsi láti ọdọ awọn àjùmọjogún káàkiri àwùjọ yóò sè’rànwọ lati se agbekalẹ àjùmọse fún awọn afojúsùn ilana náà ati lati rii wipé ó jẹ sise.
Fi àwọn irin-isẹ tó jẹ mọ àlàáfia pipẹ sipò. Bótilẹjẹpé pupọ ninu awọn ihalẹ ààbò Nàìjíríà ló nilo ìdáhùn ẹka ààbò, àwọn mìíràn se é yanjú láì máse lọ sibi kankan gẹgẹbi ìbáraẹnisọrọ ati àwọn ètò ìdàgbàsoke ọrọ ajé ọlọjọ pipẹ. Ìlànà yi yóò jási àbáyọri tó gíga ni yiyanjú aáwọ láàrin àwọn àwùjọ eyi tó dá lori èdèkòyedè lori iwa àisòótọ ni pinpin awọn ọrọ àwùjọ.
‘Kunle Adebajo njiyàn wipé ijọba Tinubu nilò lati fihàn ifẹ láti lo ìbáraẹnisọrọ fun yiyanjú ọrọ ààbò. Idayat Hassan pàrọwà “ìyipadà ọkàn kúro ni àmì sí èrè-ìdí ati ìdókòwò lẹsẹkẹsẹ sinu àwọn ètò ìgbélárugẹ àlàáfia ni ipasẹ [ẹlẹyàmẹyà ati ẹsìn]… láti dojúkọ àwọn tó nsokùnfa àìsí ààbò.” Arabirin náà sàkiyesi wipé “a nilò àwọn ètò ìlọwọsi igbélárugẹ àlàáfíà ni kíákíá ni ọpọlọpọ, tí kò bá se ni gbogbo agbègbè ìsèlú lati se ìmúdárasi iṣọkan awujọ ninu rògbòdiyàn – àwọn agbègbè tó kàn… ati lati dá padà ipele igbẹkẹlé láàárin àwọn àwùjọ.” Matthew Page se iṣedúró wipé ijọba Tinubu “se igbekalẹ ọfisi kan fún Yiyanjú Rògbòdìyàn Àwùjọ láàárin Ile-Isẹ Ààrẹ láti fètòsi atilẹhin ti isèlú ni ipele tó gajùlọ fún yiyanju lábẹlé rògbòdiyaǹ, aáwọ, ìyípadà ìdájọ, ati àwọn ise igbélarugẹ àlàáfia.”
Se ìgbéga ìlànà ibanisọrọ. Nitoripe sise ìdínkù awọn ìpènija ààbo Nàìjíríà dá lórí ifọwọsowọpọ ara ìlú, ìdiwọn gbọdọ wà ni ibanisọrọ jijagaara pẹlu awọn ara ilu lori awọn ètò ijọba lóri ààbò. Èyi kò ni í pèsè àsọyé ati nini òye awọn ètè ijọba nikan, yóò tún sèrànwọ lati jẹki awọn ara ilu náà le gbàá. Nipa nini àsepọ pẹlu awọn ara ilu nipasẹ ibanisọrọ nigbagbogbo, àwọn ipade gbọngan ilu, ati awọn pẹpẹ ohun igbéròhìn jáde, ìjọba le se imúgbòòrò si ibánisọrọ agbègbè ni gbangba, fifi ààye gba èsì, ikọnilóminú, ati awọn àbá lati ọdọ awọn ara ilú. Síwájú si, gẹgẹbi ‘Kunle Adebajo se tẹnumọ ninu isẹ àyẹwò-òtitọ tó gbẹbùn si, ètò ìbanisọrọ le sèrànwọ imukurò ìròhin ti kò tọ, àti irọ, ati àwọn itan àkọọlẹ awọn jàndùkú, ki wọn si se igbelárugẹ isọdọkan ati isọkan orilẹ-èdè.
Se ìdókòwò si imúdárasi àwọn ètò ìkìlọ ni kùtùkùtù. Sise ètò siwajusi fún titọpinpin ètò ìkìlọ ni kùtùkùtù fún ààbò awọn ilẹ Nàìjíríà pẹlu ECOWASàti awọn alábasepọ mìíràn kò se pàtàkì nikan fún isàkóso ààbò tó múnádóko sùgbọn ó kó ipa pàtàkì ni ìgbélárugẹ igbẹkẹlé pẹlu àwọn ọmọ Nàìjíríà. Nipa ifitóniléti awọn ara ilu ati dídáhùn kíákíá si ìhalẹ tó bá nyọjú, ijọba le s’àfihàn ifaraji rẹ si ààbò ati àlàáfíà àwọn èniyàn rẹ.
“Ìgbélárugẹ ìgbẹkẹlé pẹlu awọn ara ilu gbọdọ jẹ kókó ohun àkọse nigbagbogbo fún ijọba Tinubu.”
Ètò ìkìlọ ni kùtùkùtù tó se é gbẹkẹlé npèsè iwifúnni tó péye lásikò nipa awọn ewu ààbò, eyiti yóò fún awọn ara ilu ni ààyè lati se ipinnu nipa ohun ti wọn mọ, ki wọn si gbé igbésẹ isọra tó bá yẹ. Ìlànà àmójútó yi njẹki èrò igbẹkẹle ati ifinután awọn ara ilu jinlẹ si ninu agbára ìjọba láti dábòbo àwọn èniyàn rẹ. Sise àgbékalẹ ètò ìkìlọ ni kùtùkùtù ti gbogbogbòò ninu èyi ti awọn àwùjọ abẹlé ati awọn ara ilu ńkópa yóò sèrànwọ fún pipéye ati imúnádóko ètò náà, bẹẹni yóò si tún fi agbara kún ẹnikọọkan lati lọwọ ninu ààbò t’ara wọn.
Additional Resources
- Ibùdó Áfíríkà fún Àwọn Ẹkọ Ìlànà, “Jíjìnlẹ Àṣà Àmọ̀dájú Ológún ni Áfíríkà,” Àyànláàyò, December 20, 2022.
- Ibi-Ìpéjọ Ìdábòbò Áfíríkà,“Nàìjíríà jẹ ‘Àdàlù’ Àwọn Ìdáhùn ti Ààbò, Kan” ìfọrọwánilẹnuwò pẹlu Ọmọwe. Mark Duerksen, August 15, 2022.
- Ibùdó Áfíríkà fún Àwọn Ẹkọ Ìlànà, <“a href=”https://africacenter.org/spotlight/criminal-gangs-destabilizing-nigerias-north-west/”>Àwọn Ọdaràn Onijàgídíjàgan Ńṣe Wíwópalẹ Ìwọ-Oòrùn Àríwá Nàìjíríà,” Àyànláàyò, Ibùdó Áfíríkà fún Àwọn Ẹkọ Ìlànà, December 14, 2021.
- Mark Duerksen, “Orísirísi Àwọn Ìhalẹmọ Ààbò Nàìjíríà,” Àyànláàyò, Ibùdó Áfíríkà fún Àwọn Ẹkọ Ìlànà, March 30, 2021.
- Ibùdó Áfíríkà fún Àwọn Ẹkọ Ìlànà, “Orilẹ-èdè Nàìjíríà Náà àti Àìláábò,” Fídíò Ìyipotábìlì, February 17, 2021.
- Olajumoke (Jumo) Ayandele, “Dídojúkọ Rògbòdìyan Kaduna ti Nàìjíríà,” Àyànláàyò, Ibùdó Áfíríkà fún Àwọn Ẹkọ Ìlànà, February 2, 2021.
- Ibùdó Áfíríkà fún Àwọn Ẹkọ Ìlànà, “Ìdàgbàsoke Ìlànà Ààbò Orilẹ-èdè ni Áfíríkà: Ohun elo irinṣẹ fún Ìkọsilẹ àti Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀,” January 2021.
- Ibùdó Áfíríkà fún Àwọn Ẹkọ Ìlànà, “Boko Haram àti Ìpinlẹ Islámù ni Ìwọ-Oòrùn Áfíríkà Fojúsun Àwọn Òpópóna Nàìjíríà,” Infogíráfikì, December 15, 2020.
- Ibùdó Áfíríkà fún Àwọn Ẹkọ Ìlànà, “#EndSARS Ńbèèrè fún Àtúntò Àwọn Ọlọpa Nàìjíríà,” Infogíráfikì, November 10, 2020.
- Kwesi Aning àti Joseph Siegle, “Sís’àyẹwò Ìwà Àwọn Alámọ̀dájú Ẹka Ààbò Áfíríkà ti Ìran Tó Ńbọ̀,” Ìwé Ìwádìí Ibùdó Áfíríkà No. 7, Ibùdó Áfíríkà fún Àwọn Ẹkọ Ìlànà, May 2019.
- Oluwakemi Okenyodo, “Ìṣèjọba, Ìṣèsirò, àti Ààbò ni Nàìjíríà,” Ààbo Áfíríkà Ṣókí No. 31, Ibùdó Áfíríkà fún Àwọn Ẹkọ Ìlànà, June 21, 2016.
- Emile Ouédraogo, “Títẹsiwájú Iṣẹ Àmọ̀dájú Ológun ni Áfíríkà,” Ìwé Ìwádìí No. 6, Ibùdó Áfíríkà fún Àwọn Ẹkọ Ìlànà, July 2014.
- Steven Livingston, “Ìyíká Ìwífúnni ti Áfíríkà: Àwọn Ìfọkànsí fún Ìwàkiwà, Iṣẹ Ọlọpa, àti Ààbò Ará Ilú,” Ìwé Ìwádìí Ibùdó Áfíríkà No. 5, Ibùdó Áfíríkà fún Àwọn Ẹkọ Ìlànà, November 2013.
Sí i lóri: Nàìjíríà Ìṣèjọba Ẹka Ààbò Àtúnto Ẹka Àwọn Ọlọpa